|
|
Oro naa ‘Islam’ jeyo lati idi oro ‘Salama’ – ti o tumo si lati wa ni alaafia. Nitorina, Musulumi je eniyan ti o yanda ara re, ti o jowo ara re, ati ti o si gboran si ofin Olorun Atobiju. Ati ni pase ijowo ara eni yi yi o gba alaafia ati ifokanbale fun ara re. A le ripe nipa alaye yi, oro larubawa yi ‘Islam’ na tun se apejuwe awon iwa ati ihu iwasi awon anabi ati ojise Olorun Atobiju … Gbogbo won pelu Adamo, Noa, Ibrahim, Musa, Dauda, Sulaimon, Isiaka, Ismoila, Yakubu, Yohanu Onitebomi, Suleiman, Isa omo Maria, ati Muhamadu (ki Alaafia Allah wa lori gbogbo won.) Gbogbo awon okunrin wonyi, awon anabi ati ojise yi lati odo Olorun Atobiju kanna, pelu ise iranse kanna, pelu igbekale kanna, won si so nkan kanna – gboran si Olorun! E josin si Olorun Atobiju ki e si mu ere idi iwalaye yi se ati ki e se rere, a o si fun yin ni aye miran. Eyi nikan ni won so! Ma se b pe o ju eyi lo! Eyi nikan ni won so, edekede yi o wu ati akoko yi owu, tabi eni ti a ran won si – Eyi nikan ni won so.
|