|
Ni igba ti ede aiy’ede ba wa, itenumo eke, adapo iro ati asodun, fifi itumo ti ara eni si akosile awon onkowe, onkotan ati eni kokan ni o ma n se okufa eyi. Fun apeere, eje ki n fi nkankan han yin eyi ti e ti le yewo tele. Gegebi Kristiani, mo ti yewo tele ki n to di Musulumi ati pe… ko si ye mi. Ki lo de to je wipe ni gbogbo Majemu Lailai, Olorun je okan soso—Oluwa ati Oba gbogbo agbaye. Eyi si ni ofin akoko ti a fifun Mose, ko je ki enikeni josin fun ere gbigbe kan; tabi fi ori bale fun ohunkohun ni awon Orun, tabi ni Aye, tabi ninu okun – Ko gba eyi laaye. Gbogbo awon anabi so wipe Olorun kan soso ni o wa. Ni gbogbo Majemu Lailai a ntun eyi so lai mo oye igba. Ni igba to ya, lojiji a ni orisi eri merin – ihinrere merin ti a pe ni Matiu, Maku, Luku ati Johanu. Matiu wo? Maku wo? Luku wo? Johanu wo? Ihinrere merin ototo ti a ko ni iwon odun meji-din-l’adota si ara won. Ko si si eyikeyi ninu awon okunrin yi ti won ko fo wo sowopo pelu ara won ti o so oruko baba won. Ti mo ba fun o ni iwe igbowo jade lati banki lati san owo osun re ti mo si ko oruko mi lai fi oruko baba mi si nje iwo yi o gba ni owo mi? Rara, iwo ki yi o gba a… Ti olopa ba da o duro ti o si beere fun kaadi idanimo re, ti o si je wipe oruko re akoko nikan ni o wa lori re, nje eyi yi o je itewogba lodo re? Nje o le gba iwe irina oke okun pelu oruko re akoko nikan? Nje baba ati iya re fun o ni oruko eyokan? Nibo ni itan awon eniyan ni oruko eyokan se je ohun itewogba fun akosile, nibo? Ko si! Ayafi ninu Majemu Titun.
|